Clubhouse logo

Ade Aniyaplenty

@aniyaplenty

270

friends

PRAYER OF THE MONTH OF THANKSGIVING (OṢÙ ỌPẸ). Good morning to you all friend across the world, I wish you happy new month of Ọpẹ (December), may this month be a month of an abundance goodness for each and everyone of us àṣẹ. As we all known that this month is the last month of the year 2022, and it is called the month of Ọpẹ (thanksgiving), in this case we need to give glory and adoration to the living Eledumare for making us witness today 1st of December, for his grace to allow us passed those horrible and sad days, may we always have a cause to be praising you our wonderful Eledumare. Let us use this holy corpus of ogbehunle for today's prayer. Hear what the corpus said: Ọ̀rúnmìlà ni òjò palẹ̀ mọ́kẹ̀ Moni ọ̀gùdùngbẹ̀ eyìn npọdídẹ lerin cast divination for Ọlọfin (king) when things were hard, rough and tough for him, he was advised to use pig to appease òkè ìpọ̀nrí (ifá) and he complied, aftermath all things were easier for Ọlọfin to do, he didn't experience hardship in life anymore, he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifá while ifá was praising Eledumare. My people, I pray this morning that this new month of Ọpẹ (December) will never hard for us, may we be located with all good things of the life, may we never experience all the principalities of evil by the authority of the supreme creator, in the remaining of this year, bad news will never be our portions by the power of Eledumare aaaṣẹ. YORUBA VERSION. Ẹkáàrọ́ọ̀ ẹyin ènìyàn mi, aòjíire bi? Akú amojuba oṣù tuntun ọpẹ (December), oṣù ayọ àti idunnu ni yíò jẹ́ funwa o, ao ri àánú gba lóṣù yi aṣẹ. Gẹgẹbi oṣù yi ṣe jẹ oṣù to gbẹ̀yìn ninu ọdun 2022, a dupẹ lọwọ Eledumare fún àánú rẹ tofi dawasi di ọjọ́ òní, moṣe ni iwúre wípé ẹnu ọpẹ wa koni kan o, ọpẹ idunnu ni ao máa dú a koni báwọn dúpẹ́ bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ o. Ẹ jẹki a fi odù ifá mimọ Ogbehunle yi ṣe ìwúre ti àárọ̀ yi. Ifá náà kí bayi wípé: Ọ̀rúnmìlà ni òjò palẹ̀ mọ́kẹ̀ Moni Ọ̀gùdùngbẹ̀ eyìn npọdídẹ lerin a dífá fún ọlọfin lọ́jọ́ ti nfoju ẹkún nṣerahun ire gbogbo, ti gbogbo nkan le mọ ọlọfin, wọn ni ki ọlọfin káraálẹ̀ ẹbọ ni ki o wa ṣe nítorí kì o bàá jayé ìrọ̀rùn láyé, àgbá ẹlẹdẹ ni wọn ní kofi ṣe òkè ìpọ̀nrì, ọlọfin kábọmọ́ra o rúbọ wọn ṣe ṣiṣe ifá fún, látí ìgbà náà ni ọlọfin ti bẹ̀rẹ̀ sìnì njaye irọrun, nkan ko wa le mọ ọlọfin mọ, o wa njo o nyọ o nyìn babaláwo awọn babaláwo nyìn ifá, ifá nyìn Eledumare oni njẹ rírú ẹbọ a máa gbeni èrù àtùkèṣù a máa da ladaju njẹ ko pẹ ko jinna ifá wa bami laruṣẹgun aruṣẹgun ni a nbawo